Ìwé Wòlíì Amosi
1
Àwọn ọ̀rọ̀ Amosi, ọ̀kan lára àwọn olùṣọ́-àgùntàn Tekoa; ohun tí o rí nípa Israẹli ní ọdún méjì ṣáájú ilẹ̀-rírì, nígbà tí Ussiah ọba Juda àti Jeroboamu ọmọ Jehoaṣi jẹ́ ọba ní ilẹ̀ Israẹli.
 
 
Jl 3.16.Ó wí pé,
Olúwa yóò bú jáde láti Sioni,
ohùn rẹ̀ yóò sì sán bí àrá láti Jerusalẹmu wá;
ibùgbé àwọn olùṣọ́-àgùntàn yóò sì ṣọ̀fọ̀,
orí òkè Karmeli yóò sì rọ.”
Ìdájọ́ àwọn aládùúgbò Israẹli
Isa 17.1-3; Jr 49.23-27; Sk 9.1.Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta tí Damasku,
àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà.
Nítorí wọn fi ohun èlò ìpakà pa Gileadi.
Pẹ̀lú ohun èlò irin tí ó ní eyín mímú,
Èmi yóò rán iná sí ilé Hasaeli,
èyí ti yóò jó àwọn ààfin Beni-Hadadi run.
Èmi yóò ṣẹ́ ọ̀pá ìdábùú Damasku;
Èmi yóò sì pa ọba tí ó wà ní àfonífojì Afeni run
àti ẹni tí ó di ọ̀pá aládé mú ní Beti-Edeni.
Àwọn ará a Aramu yóò lọ sí ìgbèkùn sí Kiri,”
ni Olúwa wí.
Isa 14.29-31; Jr 47; El 25.15-17; Jl 3.4-8; Sf 2.4-7; Sk 9.5-7.Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta Gasa,
àní nítorí mẹ́rin,
Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà.
Gẹ́gẹ́ bí í oníṣòwò ẹrú,
ó kó gbogbo àwọn ènìyàn mi ní ìgbèkùn.
Ó sì tà wọ́n fún Edomu,
Èmi yóò rán iná sí ara odi Gasa
tí yóò jó gbogbo ààfin rẹ̀ run.
Èmi yóò ké àwọn olùgbé Aṣdodu kúrò,
ti ẹni tí ó di ọ̀pá aládé ní Aṣkeloni mú.
Èmi yóò yí ọwọ́ mi sí Ekroni
títí tí ìyókù Filistini yóò fi ṣègbé,”
ni Olúwa Olódùmarè wí.
Isa 23; El 26.1–28.19; Jl 3.4-8; Sk 9.3-4.Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Tire
àní nítorí mẹ́rin, Èmi kì yóò yí ìpinnu ìjìyà mi padà.
Nítorí wọ́n ta gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní ìgbèkùn fún Edomu.
Wọn kò sì náání májẹ̀mú ọbàkan,
10 Èmi yóò rán iná sí ara odi Tire,
tí yóò jó gbogbo àwọn ààfin rẹ̀ run.”
11  Isa 34; 63.1-6; Jr 49.7-22; El 25.12-14; 35; Od 1-9; Ml 1.2-5.Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta tí Edomu,
àní nítorí mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà.
Nítorí òhun fi idà lépa arákùnrin rẹ̀,
Ó sì gbé gbogbo àánú sọnù,
ìbínú rẹ̀ sì ń faniya títí,
ó sì pa ìbínú rẹ̀ bí èéfín mọ́,
12 Èmi yóò rán iná sí orí Temani,
tí yóò jó gbogbo ààfin Bosra run.”
13  Jr 49.1-6; El 21.28-32; 25.1-7; Sf 2.8-11.Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Ammoni,
àní mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà.
Nítorí wọn ti la inú àwọn aboyún Gileadi
kí wọ́n ba à lè fẹ ilẹ̀ wọn sẹ́yìn.
14 Èmi yóò rán iná sí ara odi Rabba
èyí tí yóò jó àwọn ààfin rẹ̀ run
pẹ̀lú ìhó ayọ̀ ní ọjọ́ ogun,
pẹ̀lú ìjì líle ni ọjọ́ àjà.
15 Ọba wọn yóò sì lọ sí ìgbèkùn,
òun àti àwọn ọmọ-aládé rẹ̀ lápapọ̀,”
ni Olúwa wí.

1:2 Jl 3.16.

1:3 Isa 17.1-3; Jr 49.23-27; Sk 9.1.

1:6 Isa 14.29-31; Jr 47; El 25.15-17; Jl 3.4-8; Sf 2.4-7; Sk 9.5-7.

1:9 Isa 23; El 26.1–28.19; Jl 3.4-8; Sk 9.3-4.

1:11 Isa 34; 63.1-6; Jr 49.7-22; El 25.12-14; 35; Od 1-9; Ml 1.2-5.

1:13 Jr 49.1-6; El 21.28-32; 25.1-7; Sf 2.8-11.