Saamu 65
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Orin.
Ìyìn ń dúró dè ọ́, Ọlọ́run, ní Sioni;
sí ọ ni a ó mú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ.
Ìwọ tí ó ń gbọ́ àdúrà,
gbogbo ènìyàn yóò sì wá sọ́dọ̀ rẹ.
Ọ̀ràn àìṣedéédéé borí mi bí ó ṣe ti ìrékọjá wa ni!
Ìwọ ni yóò wẹ̀ wọ́n nù kúrò.
Ìbùkún ni fún àwọn tí o yàn
tí o mú wa láti máa gbé àgọ́ rẹ!
A tẹ́ wá lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere inú ilé rẹ,
ti tẹmpili mímọ́ rẹ.
 
Ìwọ dá wa lóhùn pẹ̀lú ohun ìyanu ti òdodo,
Ọlọ́run olùgbàlà wa,
ẹni tí ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé gbogbo òpin ayé
àti àwọn tí ó jìnnà nínú òkun,
ìwọ tí ó dá òkè nípa agbára rẹ,
tí odi ara rẹ ní àmùrè agbára,
ẹni tí ó mú rírú omi òkun dákẹ́,
ríru ariwo omi wọn,
àti ìdágìrì àwọn ènìyàn.
Àwọn tí ó ń gbé òkèrè bẹ̀rù,
nítorí àmì rẹ wọ̀n-ọn-nì;
ìwọ mú ìjáde òwúrọ̀ àti ti àṣálẹ́ yọ̀,
ìwọ pè fún orin ayọ̀.
 
Ìwọ bẹ ayé wò, o sì bomirin;
ìwọ mú un ọ̀rọ̀ púpọ̀.
Odò Ọlọ́run kún fún omi
láti pèsè ọkà fún àwọn ènìyàn,
nítorí ibẹ̀ ni ìwọ ti yàn án.
10 Ìwọ fi bomirin sí aporo rẹ̀
ìwọ tẹ́ ògúlùtu rẹ̀;
ìwọ fi òjò mú ilẹ̀ rẹ̀ rọ̀,
o sì bùkún ọ̀gbìn rẹ̀.
11 Ìwọ fi oore rẹ dé ọdún ní adé,
ọ̀rá ń kán ní ipa ọ̀nà rẹ.
12 Pápá tútù ní aginjù ń kan
àwọn òkè kéékèèké fi ayọ̀ di ara wọn ní àmùrè.
13 Agbo ẹran ni a fi wọ pápá tútù náà ní aṣọ;
àfonífojì ni a fi ọkà bò mọ́lẹ̀,
wọ́n hó fún ayọ̀, wọ́n ń kọrin pẹ̀lú.