Saamu 56
Fún adarí orin. Ti ohùn “Àdàbà lórí Óákù òkè réré.” Ti Dafidi. Miktamu. Nígbà tí àwọn ará Filistini ka mọ́ ní Gati.
1 Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run,
nítorí àwọn ènìyàn ń fi ìgbónára lépa mi;
ní gbogbo ọjọ́ ni wọn ń kọjú ìjà sí mi, wọn ń ni mi lára.
2 Àwọn ọ̀tá mi ń lé mi ní gbogbo ọjọ́,
àwọn ènìyàn ń kọjú ìjà sí mi nínú ìgbéraga wọn.
3 Nígbà tí ẹ̀rù bà ń bà mí,
èmi o gbẹ́kẹ̀lé ọ.
4 Nínú Ọlọ́run èmi yóò máa yìn ọ̀rọ̀ rẹ,
nínú Ọlọ́run ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi; ẹ̀rù kì yóò bà mí
kí ni ẹran-ara lè ṣe sí mi?
5 Wọn ń yí ọ̀rọ̀ mí ní gbogbo ọjọ́,
wọn ń gbèrò nígbà gbogbo láti ṣe mí níbi.
6 Wọn kó ara wọn jọ, wọ́n ba.
Wọ́n ń ṣọ́ ìgbésẹ̀ mi
wọn ń làkàkà láti gba ẹ̀mí mi.
7 San ẹ̀san iṣẹ́ búburú wọ́n fún wọn;
ní ìbínú rẹ, Ọlọ́run, wọ́ àwọn ènìyàn náà bọ́ sílẹ̀.
8 Kọ ẹkún mi sílẹ̀;
kó omijé mi sí ìgò rẹ,
wọ́n kò ha sí nínú ìkọ̀sílẹ̀ rẹ bí?
9 Nígbà náà ni àwọn ọ̀tá mi yóò pẹ̀yìndà
nígbà tí mo bá pè fún ìrànlọ́wọ́
nípa èyí ni mo mọ̀ pé Ọlọ́run ń bẹ fún mi.
10 Nínú Ọlọ́run, ẹni tí mo yìn ọ̀rọ̀ rẹ̀
nínú Olúwa, ẹni tí mo yin ọ̀rọ̀ rẹ̀,
11 nínú Ọlọ́run ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi:
ẹ̀rù kì yóò bà mí.
Kí ni ènìyàn lè ṣe sí mi?
12 Mo jẹ́ ẹ̀jẹ́ lábẹ́ rẹ Ọlọ́run:
èmi o mú ìyìn mi wá fún ọ.
13 Nítorí ìwọ tí gbà mí lọ́wọ́ ikú
àti ẹsẹ̀ mi lọ́wọ́ ìṣubú,
kí èmí lè máa rìn níwájú Ọlọ́run
ní ìmọ́lẹ̀ àwọn alààyè.