Saamu 46
Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Gẹ́gẹ́ bí ti alamoti. Orin.
Ọlọ́run ni ààbò àti agbára wa
ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ ní ìgbà ìpọ́njú.
Nítorí náà àwa kì yóò bẹ̀rù, bí a tilẹ̀ ṣí ayé ní ìdí,
tí òkè sì ṣubú sínú Òkun.
Tí omi rẹ̀ tilẹ̀ ń hó tí ó sì ń mì
tí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ń mì pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀.
Sela.
 
Odò ńlá kan wà tí ṣíṣàn rẹ̀ mú inú ìlú Ọlọ́run dùn,
ibi mímọ́, níbi ti Ọ̀gá-ògo ń gbé.
Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀, kò ní yẹ̀:
Ọlọ́run yóò ràn án lọ́wọ́ ní kùtùkùtù òwúrọ̀.
Àwọn orílẹ̀-èdè ń bínú, àwọn ilẹ̀ ọba ṣubú,
ó gbé ohun rẹ̀ sókè, ayé yọ̀.
 
Olúwa àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú wa,
Ọlọ́run Jakọbu ni ààbò wa.
 
Ẹ wá wo iṣẹ́ Olúwa
irú ahoro tí ó ṣe ní ayé.
O mú ọ̀tẹ̀ tán de òpin ilẹ̀ ayé
ó ṣẹ́ ọrun, ó sì gé ọ̀kọ̀ sí méjì
ó fi kẹ̀kẹ́ ogun jóná.
10 Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ní Ọlọ́run.
A ó gbé mi ga nínú àwọn orílẹ̀-èdè,
a ó gbé mi ga ní ayé.
 
11  Olúwa àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú wa;
Ọlọ́run Jakọbu sì ni ààbò wa.